Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 15:31-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í sẹ̀sín láàrin ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà.

32. Jẹ́ kí Kírísítì, Ọba Ísírẹ̀lì, sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.

33. Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsàn-án.

34. Ní wákàtí kẹsàn-án ni Jésù kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “ÈLÓÍ, ÈLÓÍ, LÀMÁ SÀBÁKÍTANÍ?” ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”

35. Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Èlíjà.”

36. Nígbà náà ni ẹnìkan wá sáré lọ ki kàn-ìn-kàn-ìn bọ inú ọtí kíkan, ó fi lé orí ọ̀pá, ó sì nà án sí Jésù kí ó lè mu ún. Ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a máa wò ó, bóyá Èlíjà yóò wá sọ̀ ọ́ kalẹ̀.”

37. Jésù sì tún kígbe soke ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.

38. Aṣọ ìkélé tẹ́ḿpìlì sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀.

39. Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jésù rí i tí kígbe sókè báyìí tí ó sì èémí ìgbẹ̀yìn, ó wí pé, “Dájúdájú Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í se.”

40. Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń najú wò ó láti òkèèrè. Màríà Magidalénì wà lára àwọn obìnrin náà, àti Màríà ìyá Jákọ́bù kékeré àti ti Jósè àti, Ṣálómè.

41. Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Gálílì máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìranṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerúsálémù.

42. Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ (èyí tí se, ọjọ́ tó sáájú ọjọ́ ìsinmi). Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú,

43. Jóṣẹ́fù ará Arimatíyà wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pílátù láti tọrọ òkú Jésù.

44. Ẹnú ya Pílátù láti gbọ́ pé Jésù ti kú. Nítorí náà ó pe balógun-ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jésù ti kú ní tòótọ́.

45. Nígbà tí balógun-ọ̀rún náà sì fún Pílátù ni ìdánilójú pé Jésù ti kú, Pílátù yọ̀ǹda òkú rẹ̀ fún Jóṣẹ́fù.

46. Jóṣẹ́fù sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jésù kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.

Ka pipe ipin Máàkù 15