Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 15:20-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nígbà tí wọ́n sì fi ṣẹ̀sín tan, wọ́n sì bọ aṣọ elésè àlùkò náà kúrò lára rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un jáde lọ láti kàn án mọ́ àgbélébùú.

21. Wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń kọjá lọ. Símónì ni orúkọ rẹ̀. Ará Kírénì ni. Òun ni baba Alekisáńdérù àti Rúfọ́ọ̀sì. Wọ́n sì mú un nípá, pé kí ó rú àgbélébùú Jésù.

22. Wọ́n sì mú Jésù wá sí Gọ́lgọ́tà, (èyí tí ìtúmọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ibi Agbárí)

23. Wọ́n sì fi wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á.

24. Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrin ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn báà lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù.

25. Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú.

26. Àkọlé Ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni ỌBA ÀWỌN JÚÙ.

27. Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀.

28. Eléyìí mú àṣọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, “Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú.”

29. Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Áà! Ìwọ tí yóò wó tẹ́ḿpìlì tí yóò sì tún un kọ́ láàrin ọjọ́ mẹ́ta.

30. Tí ó bá lágbára tó bẹ́ẹ̀, gba ara rẹ là, kí o sì ti orí àgbélébùú sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú.”

31. Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í sẹ̀sín láàrin ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà.

32. Jẹ́ kí Kírísítì, Ọba Ísírẹ̀lì, sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.

33. Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsàn-án.

34. Ní wákàtí kẹsàn-án ni Jésù kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “ÈLÓÍ, ÈLÓÍ, LÀMÁ SÀBÁKÍTANÍ?” ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”

35. Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ gbọ́, wọ́n sì wí pé, “Wò ó ó ń pe Èlíjà.”

Ka pipe ipin Máàkù 15