Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 14:45-60 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

45. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, Júdásì lọ sì ọ̀dọ̀ rẹ̀ tààrá, ó wí pé, “Rábì!” ó sì fi ẹnu kò Jésù lẹ́nu.

46. Wọ́n sì mú Jésù.

47. Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró idà rẹ̀ yọ, ó fi sá ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ge etí rẹ̀ bọ́ sílẹ̀.

48. Nígbà náà Jésù dáhùn, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé Èmi ni ẹ̀yin jáde tọ̀ wá bi olè, ti ẹ̀yin ti idà àti kùmọ̀ láti mú?

49. Ojoojúmọ́ ni èmi wà pẹ̀lú yín ní tẹ́ḿpìlì, tí mo ń kọ́ni; ẹ kò mú mi. Ṣùgbọ́n eléyìí ṣẹlẹ̀, kí ohun tí ìwé Mímọ́ wí lè ṣẹ.”

50. Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti fi í sílẹ̀, wọ́n sá lọ.

51. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ bo ìhòòhò rẹ̀ àwọn ọmọ-ogun gbìyànjú láti mú òun náà.

52. Ó sì fi aṣọ funfun náà sílẹ̀ fún wọn, ó sì sá lọ ní ìhòòhò.

53. Wọ́n mú Jésù lọ sí ilé olórí àlùfáà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù àti àwọn olùkọ́-òfin wọn péjọ síbẹ̀.

54. Pétérù tẹ̀lé Jésù lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná.

55. Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rí èkè sí Jésù, èyí tí ó jọjú dáadáa láti lè dájọ́ ikú fún un. Ṣùgbọ́n wọn kò rí.

56. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ̀n ní kò bá ara wọn mu

57. Níkẹyìn àwọn kan dìde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ní

58. “A gbọ́ tí ó wí pé ‘Èmi yóò wó tẹ́ḿpìlì tí ẹ fi ọwọ́ kọ́ yìí, nígbà tí yóò bá sì fi di ọjọ́ kẹta, èmi yóò kọ́ òmíràn ti a kò fi ọwọ́ ènìyàn kọ́.’ ”

59. Ṣíbẹ̀, ẹ̀rí i wọn kò dọ́gba

60. Nígbà náà ni àlùfáà àgbà dìde, ó bọ́ ṣíwájú. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi Jésù léèrè, ó ní, “Ṣé o kò ní fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn ọ? Kí ni ìwọ gan an ní sọ fúnrarẹ?”

Ka pipe ipin Máàkù 14