Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 14:23-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ó sì tún gbé ago wáìnì, ó gbàdúrà ọpẹ́ sí Ọlọ́run. Ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.

24. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi ti májẹ̀mú túntún, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

25. Lóótọ̀ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní titun nínú ìjọba Ọlọ́run.”

26. Lẹ́yìn náà wọ́n kọ orin, wọ́n sì gun orí òkè ólífì lọ.

27. Jésù sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ ń bọ̀ wá kosẹ̀ lára mi ni oru òní, a ti kọ̀wé rẹ pé:“ ‘Èmi yóò lu olùsọ́-àgùntànàwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká.’

28. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, Èmi yóò ṣíwájú yin lọ sí Gálílì.”

29. Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn, ó wí pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá.”

30. Jésù wá wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tóó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ̀ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”

31. Ṣùgbọ́n Pétérù faraya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́ rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.

32. Nígbà tí wọ́n dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní ọgbà Gétísémánì. Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó dè mí níhìnín títí n ó fi lọ gbàdúrà.”

33. Ó sì mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi.

34. Ó sì wí fún wọn pé, “Títí dé kú. Ẹ dúró níhìnín kí ẹ sì máa mi sọ́nà.”

35. Ó sì lọ ṣíwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá.

36. Ó sì wí pé, “Á bà Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kìí ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò se èyí tí ìwọ fẹ́.”

37. Nígbà tí ó sì páda dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Pétérù pé, “Símónì, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi sọ́nà fún wákàtí kan?

38. Ẹ máa sọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ”

39. Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú.

40. Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ì bá fún un.

41. Ó sì wá nígbà kẹ́ta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́.

42. Ẹ dìde, Ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòòsí!”

43. Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, lójú ẹsẹ̀ náà ni Júdásì ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá dé pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti idà àti kùmọ́ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà, àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn àgbààgbà Júù ni ó rán wọn wa.

Ka pipe ipin Máàkù 14