Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 1:23-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ní àsìkò náà gan-an ni ọkùnrin kan tí ó wà nínú sínágọ́gù wọn, tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe wí pé,

24. “Kí ni ìwọ ń wá lọ́dọ̀ wa, Jésù ti Násárẹ́tì? Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ìwọ ní ẹni Mímọ́ Ọlọ́run!”

25. Jésù si bá a wí, ó wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí ó sì jáde kúro lára rẹ̀.”

26. Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì gbé e sánlẹ̀ lógèdèǹgbé, ó ké ní ohùn rara, ó sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà.

27. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ń sọ láàrin ara wọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n béèrè pẹ̀lú ìgbóná ara, pé, “Kí ni èyí? Irú ẹ̀kọ́ titun wo ni èyí? Ó ń fi agbára pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá wọ́n sì gbọ́ tirẹ̀.”

28. Ìròyìn nípa rẹ̀ tàn ká gbogbo agbégbé Gálílì.

29. Nígbà tí wọn sì jáde kúrò nínú sínágọ́gù, wọ́n lọ pẹ̀lú Jákọ́bù àti Jòhánù sí ilé Símónì àti Ańdérù.

30. Ìyá ìyàwó Símónì tí ó dùbúlẹ̀ àìsàn ibà, wọ́n sì sọ fún Jésù nípa rẹ̀.

31. Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó fà á lọ́wọ́, ó sì gbé e dìde; lójú kan náà ibà náà fi sílẹ̀, ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

32. Nígbà tí ó di àṣálẹ́, tí òòrùn wọ̀, wọ́n gbé gbogbo àwọn aláìsàn àti àwọn tó ni ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá.

33. Gbogbo ìlú si péjọ ni ẹnu-ọ̀nà.

34. Jésù sì wo ọ̀pọ̀ tí wọ́n ní onírúurú aláìsàn sàn. Bákan náà ni ó lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àìmọ́ jáde, Ṣùgbọ́n kò sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà kí ó sọ̀rọ̀, nítorí tí wọ́n mọ ẹni tí òun í se.

35. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ilẹ̀ tó mọ́, Jésù nìkan jáde lọ sí ihà kan, láti lọ gbàdúrà.

36. Símónì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ yòókù lọ láti wá a.

37. nígbà tí wọ́n sì rí I, wọ́n sọ fún wí pé, “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ!”

38. Jésù sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.”

Ka pipe ipin Máàkù 1