Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 6:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ ìsinmi kan, Jésù ń kọjá láàrin oko ọkà; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń ya ìpẹ́ ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́.

2. Àwọn kan nínú àwọn Farisí sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe èyí tí kò yẹ láti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi?”

3. Jésù sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò kà nípa ohun tí Dáfídì ṣe, nígbà tí ebi ń pa òun tìkárarẹ̀ àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀;

4. ó ti wọ ilé Ọlọ́run lọ, tí ó sì mú àkàrà ìfihàn tí ó sì jẹ ẹ́, tí ó sì fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú; tí kò yẹ fún un láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà níkan ṣoṣo?”

5. Ó sì wí fún wọn pé, “Ọmọ ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi.”

6. Ní ọjọ́ ìsinmi mìíràn, ó wọ inú sínágọ́gù lọ, ó sì ń kọ́ni, ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún rọ.

7. Àti àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí ń ṣọ́ ọ, bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi; kí wọn lè rí ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kàn án.

8. Ṣùgbọ́n ó mọ ìrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde, kí o sì dúró láàrin.” Ó sì dìde dúró.

9. Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Èmi bi yín léèrè, Ó ha tọ́ láti máa ṣe rere ni ọjọ́ ìsinmi, tàbí láti máa ṣe búburú? Láti gba ọkàn là, tàbí láti pa á run?”

10. Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká, ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀: ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí èkejì.

11. Wọ́n sì kún fún ìbínú gbígbóná; wọ́n sì bá ara wọn rò ohun tí àwọn ìbá ṣe sí Jésù.

12. Ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọnnì, Jésù lọ sí orí òkè lọ gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run.

13. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; nínú wọn ni ó sì yan méjìlá, tí ó sì sọ ní àpósítélì.

14. Símónì (ẹni tí a pè ní Pétérù) àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, Jákọ́bù àti Jòhánù, Fílípì àti Batolóméù.

Ka pipe ipin Lúùkù 6