Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 5:4-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ í sọ, ó wí fún Símónì pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”

5. Símónì sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”

6. Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya.

7. Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà ní ọkọ̀ kéjì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.

8. Nígbà tí Símónì Pétérù sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bá eékún Jésù, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́sẹ̀ ni mí.”

9. Ẹnu sì yàá wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó:

10. Bẹ́ẹ̀ ni Jákọ́bù àti Jòhánù àwọn ọmọ Sébédè, tí ń ṣe alábàákẹ́gbẹ́ Símónì.Jésù sì wí fún Símónì pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa sàwárí àwọn ẹlẹ́sẹ̀.”

11. Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ.

12. Ó sì ṣe, nígbà tí Jésù wọ ọ̀kan nínú àwọn ìlú náà, kíyèsí i, ọkùnrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò: nígbà tí ó rí Jésù, ó wólẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mí di mímọ́.”

13. Jésù sì na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́!” Lójúkan náà ẹ̀tẹ̀ sì fi í sílẹ̀ lọ.

14. Ó sì kìlọ̀ fún u pé, “Kí ó má ṣe sọ fún ẹnìkan: ṣùgbọ́n kí ó lọ, kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí ó sì ta ọrẹ fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Mósè ti pàṣẹ fún ẹ̀rí sí wọn.”

15. Ṣùgbọ́n òkìkí rẹ̀ ń kàn kálẹ̀: tóbẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì jùmọ̀ pàdé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba dídá ara lọ́dọ̀ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlera wọn.

16. Ṣùgbọ́n ésù a máa yẹra kúrò, òun á sì máa dáwà láti gbàdúrà.

17. Ní ijọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisí àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Gálílì gbogbo, àti Jùdíà, àti Jerúsálémù wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá.

18. Sáà sì kíyèsí i, àwọn Ọkùnrin kan gbé ẹnikantí ó ní àrùn egba wà lórí àketè: wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ ṣíwájú Jésù.

19. Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àketè rẹ̀ níwájú Jésù.

20. Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” (Luk 7.48,49.)

21. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í gbérò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀ òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.” (Isa 43.25.)

22. Jésù sì mọ ìrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?

23. Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti wí pé, ‘Dìde kí ìwọ sì má a rìn’?

Ka pipe ipin Lúùkù 5