23. Nígbà tí wọn kò sì rí òkú rẹ̀, wọ́n wá wí pé, àwọn rí ìran àwọn ańgẹ́lì tí wọ́n wí pé, ó wà láàyè.
24. Àti àwọn kan tí wọ́n wà pẹ̀lú wa lọ sí ibojì, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí àwọn obìnrin náà ti wí: ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ ni wọn kò rí.”
25. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tí òye kò yé, tí ẹ sì yigbì ní àyà láti gba gbogbo èyí tí àwọn wòlíì ti wí gbọ́:
26. Kò ha yẹ kí Kírísítì ó jìyà nǹkan wọ̀nyí kí ó sì wọ inú ògo rẹ̀ lọ.”
27. Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti Mósè àti gbogbo àwọn wòlíì wá, ó sì túmọ̀ nǹkan fún wọn nínú ìwé mímọ́ gbogbo nípa ti ara rẹ̀.
28. Wọ́n sì súnmọ́ ìletò tí wọ́n ń lọ: ó sì ṣe bí ẹni pé yóò lọ sí iwájú.
29. Wọ́n sì rọ̀ ọ́, pé, “Bá wa dúró: nítorí ó di ọjọ́ alẹ́, ọjọ́ sì kọjá tán.” Ó sì wọlé lọ, ó bá wọn dúró.
30. Ó sì ṣe, bí ó ti bá wọn jókòó ti oúnjẹ, ó mú àkàrà, ó súre sí i, ó sì bù ú, ó sì fifún wọn.
31. Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú
32. Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”
33. Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn,
34. Èmí wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Símónì!”
35. Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mímọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.