Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 22:31-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Olúwa sì wí pé, “Símónì, Símónì, wò ó, Sàtánì fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí àlìkámà:

32. Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.”

33. Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.”

34. Ó sì wí pé, “Mo wí fún ọ, Pétérù, àkùkọ kì yóò kọ lónìí-ín tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí.”

35. Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí mo rán yín lọ láìní àpò-owó, àti àpò, àti bàtà, ọ̀dá ohun kan dá yín bí?”Wọ́n sì wí pé, “Rárá!”

36. Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú; ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ìkan.

37. Nítorí mo wí fún yín pé, ‘Èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ lára mi, A sì kà á mọ́ àwọn arúfin.’ Nítorí àwọn ohun wọ̀nyí nípa ti èmi yóò ní ìmúṣẹ.”

38. Wọ́n sì wí pé, “Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhín-ín yìí!”Ó sì wí fún wọn pé, “Ó tó.”

39. Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè ólífì, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

40. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwọ̀.”

41. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà.

42. Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, gba ago yìí lọ́wọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.”

43. Ańgẹ́lì kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú.

44. Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.

45. Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá ó bá wọn, wọ́n ń sùn fún ìbànújẹ́.

46. Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹ́wò.”

47. Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsí i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Júdásì, ìkan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jésù láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

Ka pipe ipin Lúùkù 22