Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 20:7-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Wọn kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”

8. Jésù sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ èmi kì yóò wí fún yín àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí.”

9. Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùsọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́.

10. Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùsọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èṣo ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

11. Ó sì tún rán ọmọ-ọ̀dọ̀ míràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ níyà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

12. Ó sì tún rán ẹ̀kẹ́ta: wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.

13. “Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn ó ṣojúsájú fún un.’

14. “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbérò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’

15. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tìí jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.“Ǹjẹ́ kínni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn?

16. Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri I!”

17. Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,Òun náà ni ó di pàtàkì igun kilé’?

18. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá subú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”

19. Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.

20. Wọ́n sì ń sọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn amí tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtọ́ ènìyàn, kí wọn baà lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn baà lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́.

21. Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣojúsájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lótítọ́.

22. Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó-òde fún Késárì, tàbí kò tọ́?”

Ka pipe ipin Lúùkù 20