Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 20:19-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.

20. Wọ́n sì ń sọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn amí tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtọ́ ènìyàn, kí wọn baà lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn baà lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́.

21. Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣojúsájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lótítọ́.

22. Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó-òde fún Késárì, tàbí kò tọ́?”

23. Ṣùgbọ́n ó kíyèsí àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé,

24. “Ẹ fi owó-idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti tani ó wà níbẹ̀?”

25. Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Késárì ni.”Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Késárì fún Késárì, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

26. Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.

27. Àwọn Ṣadusí kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í,

28. Wí pé, “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀.

29. Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ.

30. Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ.

31. Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú.

32. Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú.

33. Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya tìtani yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sáà ni ín ní aya.”

34. Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún-ni.

35. Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún-ni.

36. Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn áńgẹ́lì dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde.

37. Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mósè tìkararẹ̀ sì ti fihàn ní ìgbẹ́, nígbà tí ó pe Olúwa ni Ọlọ́run Ábúráhámù, àti Ọlọ́run Ísáákì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù.

38. Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láàyè fún un.”

Ka pipe ipin Lúùkù 20