Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 20:18-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá subú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”

19. Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.

20. Wọ́n sì ń sọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn amí tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtọ́ ènìyàn, kí wọn baà lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn baà lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́.

21. Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣojúsájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lótítọ́.

22. Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó-òde fún Késárì, tàbí kò tọ́?”

23. Ṣùgbọ́n ó kíyèsí àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé,

24. “Ẹ fi owó-idẹ kan hàn mí. Àwòrán àti àkọlé ti tani ó wà níbẹ̀?”

25. Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ti Késárì ni.”Ó sì wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tí i ṣe ti Késárì fún Késárì, àti ohun tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

26. Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.

27. Àwọn Ṣadusí kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í,

28. Wí pé, “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀.

29. Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ.

30. Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ.

Ka pipe ipin Lúùkù 20