Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lúùkù 16:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú pé, “Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà, tí ó ní ìríjú kan; òun náà ni wọ́n fi sùn ún pé, ó ti ń fi ohun-ìní rẹ̀ ṣòfò.

2. Nígbà tí ó sì pè é, ó wí fún un pé, ‘Èéṣe tí èmi fi ń gbọ́ èyí sí ọ? ṣírò iṣẹ́ ìríjú rẹ; nítorí ìwọ kò lè ṣe ìríjú mọ́.’

3. “Ìríjú náà sì wí nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Nítorí tí olúwa mi gba iṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ mi: èmi kò lè walẹ̀; láti sàgbẹ̀ ojú ń tì mí.

4. Mo mọ èyí tí èmi yóò se, nígbà tí a bá mú mi kúrò níbi isẹ́ ìríjú, kí wọn kí ó le gbà mí sínú ilé wọn.’

5. “Ó sì pe àwọn ajigbèsè olúwa rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí fún èkínní pé, ‘Èló ni ìwọ jẹ olúwa mi?’

6. “Ó sì wí pé, ‘Ọgọ́rùn-ún Òṣùwọ̀n òróró.’“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, sì jókòó nísinsin yìí, kí o sì kọ àádọ́ta.’

7. “Nígbà náà ni ó sì bi ẹnìkejì pé, ‘Èló ni ìwọ́ jẹ?’“Òun sì wí pé, ‘Ọgọ́rùnún òsùwọ̀n àlìkámà.’“Ó sì wí fún un pé, ‘Mú ìwé rẹ, kí o sì kọ ọgọ́rin.’

8. “Olúwa rẹ̀ sì yin aláìṣòótọ́ ìríjú náà, nítorí tí ó fi ọgbọ́n ṣe é: àwọn ọmọ ayé yìí sáà gbọ́n ní Ìran wọn ju àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ lọ.

9. Èmi sì wí fún yín, ẹ fi mámónì àìṣòótọ́ yan ọ̀rẹ́ fún ara yín pé, nígbà tí yóò bá yẹ, kí wọn kí ó le gbà yín sí ibùjókòó wọn títí ayé.

10. “Ẹni tí ó bá ṣe olóòótọ́ ní ohun kínkinní, ó ṣe olóòótọ́ ní púpọ̀ pẹ̀lú: ẹni tí ó bá sì ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun kínkinní, ó ṣe aláìṣòótọ́ ní ohun púpọ̀ pẹ̀lú.

11. Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò bá ti jẹ́ olóòótọ́ ní mámónì àìṣòótọ́, tani yóò fi ọ̀rọ̀ tòótọ́ ṣú yín?

12. Bí ẹ̀yin kò bá sì ti jẹ́ olóòtítọ́ ní ohun tí í se ti ẹlòmíràn, tani yóò fún yín ní ohun tí í se ti ẹ̀yin tìkara yín?

13. “Kò sí ìránṣẹ́ kan tí ó le sin olúwa méjì: àyàfi kí ó kórìíra ọ̀kan, yóò sì fẹ́ èkejì; tàbí yóò fi ara mọ́ ọ̀kan yóò sì yan èkejì ní ìpọ̀sì. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run pẹ̀lú mámónì.”

14. Àwọn Farisí, tí wọ́n ní ojúkòkòrò sì gbọ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọ́n sì yọ sùtì sí i.

Ka pipe ipin Lúùkù 16