Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kólósè 2:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń jìjàkadì fún un yín àti fún àwọn ará Laodékíà àti fún ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn tí wọn kò ì tí ì rí mi sójú rí.

2. Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ lè ní ìjìnlẹ̀ ìrírí ìmọ́ Kírísítì pẹ̀lú òye àti ìmọ̀ tó dájú ṣáká. Nítorí nísinsinyìí, Ọlọ́run ti fi àṣírí ètò hàn. Ìjìnlẹ̀ àṣírí ètò náà ni Kírísítì fúnrarẹ̀.

3. Nínú ẹni tí a fi gbogbo ìsùra ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ pamọ́ sí.

4. Mo sọ èyí fún un yín kí ẹnikẹ́ni ma baà fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú yín sìnà.

5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí i lọ́dọ̀ yín nínú ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ni mo sì ń yọ̀ láti kíyèsí ètò yín àti bí ìdúró sinsin yín nínú Kírísítì ti rí.

6. Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jésù Kírísítì gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀.

7. Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé e yín ró nínú rẹ̀, ẹ máa se alágbára nínú ìgbàgbọ́, bí a ti ṣe kọ́ ọ yín, àti kí ẹ sì máa ṣàn bí omi pẹ̀lú ọpẹ́.

8. Ẹ máa kiyesii pé ẹnikẹ́ni kò fi ìmọ̀ àti ẹtan asan ko yín ní ìgbèkùn, èyí tí ó jẹmọ́ ìtàn ènìyàn bi ìpilẹ̀sẹ ẹ̀kọ́ ayé láìse ohun tí Kírísítì ti wí.

9. Nítorí nínú Kírísítì ni àti rí ẹ̀kún ìwà Ọlọ́run ní ipò ara,

10. ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kírísítì, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ.

11. Nínú ẹni tí a kò fí ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní Ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kírísítì.

Ka pipe ipin Kólósè 2