Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 8:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Jésù sì nà rọ́, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, àwọn (olùfisùn rẹ) dà? Kò sí ẹnìkan tí ó dá ọ lẹ́bi?”

11. Ó wí pé, “Kò sí ẹnìkan, Olúwa.”Jésù wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà kò dá ọ lẹ́bi: má a lọ, láti ìgbà yìí lọ, má dẹ́sẹ̀ mọ́.”

12. Jésù sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

13. Nítorí náà àwọn Farisí wí fún un pé, “Ìwọ ń jẹ́rí ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òtítọ́.”

14. Jésù dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo tilẹ̀ ń jẹ́rí fún ara mi, òtítọ́ ni ẹ̀rí mi: nítorí tí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mo ń lọ; ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò lè mọ ibi tí mo ti wá, àti ibi tí mo ń lọ.

15. Ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ nípa ti ara; èmi kò ṣe ìdájọ́ ẹnikẹ́ni.

16. Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni: nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi.

17. A sì kọ ọ́ pẹ̀lú nínú òfin pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì.

18. Èmi ni ẹni tí ń jẹ́rí ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rí mi.”

19. Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Níbo ni Baba rẹ wà?”Jésù dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi: ìbá ṣe pé ẹ̀yin mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá sì ti mọ Baba mi pẹ̀lú.”

20. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Jésù sọ níbi ìṣúra, bí ó ti ń kọ́ni ní tẹ́ḿpìlì: ẹnikẹ́ni kò sì mú un; nítorí wákàtí rẹ̀ kò tíì dé.

21. Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: ibi tí èmi gbé ńlọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.”

Ka pipe ipin Jòhánù 8