Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 7:34-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”

35. Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárin àwọn Hélénì tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Hélenì bí.

36. Ọ̀rọ̀ kí ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?”

37. Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jésù dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òrùgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu.

38. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé-mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.”

39. (Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà: nítorí a kò tí ì fi ẹ̀mí mímọ́ fúnni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jésù lógo.)

40. Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”

41. Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kírísítì náà.”Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kírísítì yóò ha ti Gálílì wá bí?

42. Ìwé-mímọ́ kò ha wí pé, Kírísítì yóò ti inú irú ọmọ Dáfídì wá, àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìlú tí Dáfídì ti wá?”

43. Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàárin ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀.

44. Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.

45. Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹ́ḿpìlì padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”

46. Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!”

47. Nítorí náà àwọn Farisí dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí?

48. Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisí ti gbà á gbọ́ bí?

49. Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.”

50. Nikodémù ẹni tí ó tọ Jésù wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé,

51. “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”

52. Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Gálílì bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Gálílì dìde.”

Ka pipe ipin Jòhánù 7