Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 7:31-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbàágbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kírísítì náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ àmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”

32. Àwọn Farisí gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisí àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn onísẹ́ lọ láti mú un.

33. Nítorí náà Jésù wí fún wọn pé, “Níwọ̀n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi.

34. Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”

35. Nítorí náà ni àwọn Júù ń bá ara wọn sọ pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí yóò gbé lọ tí àwa kì yóò fi rí i? Yóò ha lọ sí àárin àwọn Hélénì tí wọ́n fọ́n káàkiri, kí ó sì máa kọ́ àwọn Hélenì bí.

36. Ọ̀rọ̀ kí ni èyí tí ó sọ yìí, ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ kì yóò sì rí mi, àti ibi tí èmi bá wà ẹ̀yin kì yóò le wà?”

37. Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jésù dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òrùgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu.

38. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé-mímọ́ ti wí, láti inú rẹ̀ ni odò omi ìyè yóò ti máa sàn jáde wá.”

39. (Ṣùgbọ́n ó sọ èyí ní ti ẹ̀mí, tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ ń bọ̀ wá gbà: nítorí a kò tí ì fi ẹ̀mí mímọ́ fúnni; nítorí tí a kò tí ì ṣe Jésù lógo.)

Ka pipe ipin Jòhánù 7