7. Jésù wí fún àwọn ìránṣẹ́ náà pé, “Ẹ pọn omi kún ìkòkò wọ̀nyí.” Wọ́n sì pọn omi kún wọn títí dé etí.
8. Lẹ́yìn náà ni ó wí fún wọn pé, “Ẹ bù jáde lára rẹ̀ kí ẹ sì gbé e tọ olórí àsè lọ.”Wọ́n sì gbé e lọ;
9. Olórí àsè náà tọ́ omi tí a sọ di wáìnì wò. Òun kò sì mọ ibi tí ó ti wá, ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ tí ó bu omi náà wá mọ̀. Olórí àsè sì pe ọkọ ìyàwó sí apákan,
10. Ó sì wí fún un pé, “Olúkúlùkù a máa kọ́kọ́ gbé wáìnì tí ó dára jùlọ kalẹ̀; nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì mu ún yó tan, nígbà náà níí wọ́n a mú èyí tí kò dára tó bẹ́ẹ̀ wá; ṣùgbọ́n ìwọ ti pa wáìnì dáradára yìí mọ́ títí ó fi di ìsinyìí.”
11. Èyí jẹ́ àkọ́se iṣẹ́ àmì rẹ̀, tí Jésù ṣe ní Kánà ti Gálílì. Ó sì fi ògo rẹ̀ hàn; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.
12. Lẹ́yìn èyí, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kápérnámù, Òun àti Ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀: wọ́n sì gbé ibẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.
13. Àjọ-ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, Jésù sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù,
14. Ó sì rí àwọn tí n ta màlúù, àti àgùntàn, àti àdàbà, àti àwọn onípàsípàrọ̀ owó ní tẹ́ḿpìlì wọ́n jòko:
15. Ó sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo wọn jáde kúrò nínú tẹ́ḿpílì, àti àgùntàn àti màlúù; ó sì da owó àwọn onípàṣípàrọ̀ owó nù, ó sì bi tábìlì wọn ṣubú.
16. Ó sì wí fún àwọn tí ń ta àdàbà pé, “Ẹ gbé nǹkan wọ̀nyí kúrò níhín; ẹ má ṣe sọ ilé Baba mi di ilé ọjà títà.”
17. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì rántí pé, a ti kọ ọ́ pé, “Ìtara ilé rẹ jẹ mí run.”