Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 14:5-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Tómásì wí fún un pé, “Olúwa, a kò mọ ibi tí ìwọ ń lọ, a ó ha ti ṣe mọ ọ̀nà náà?”

6. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípaṣẹ̀ mi.

7. Ìbáṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú: láti ìsinsinyìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”

8. Fílípì wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.”

9. Jésù wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ fílípì? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba: Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’

10. Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, Èmi wà nínu Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

11. Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi: bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn iṣẹ́ náà pàápàá!

12. Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.

13. Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, oun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ.

14. Bí ẹ̀yin bá bèèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é.

15. “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́.

16. Nígbà náà èmi yóò wá bèèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé

17. Òun ni Ẹ̀mí Mímọ́ òtítọ́. Ayé kò le gbà á. Ṣé ayé kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò rí i rí. Ẹ̀yin mọ̀ ọn nítorí láti ìgbà tí ẹ ti wà pẹ̀lú mí. Òun náà ti wà pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan yóò wọ inú yín láti máa gbé ibẹ̀.

18. Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìní Òlùtùnú, kí ẹ wá dàbí ọmọ tí kò ní òbí. Rárá o! Mo tún ń tọ̀ yín bọ̀.

Ka pipe ipin Jòhánù 14