Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 11:19-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Màta àti Màríà láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn.

20. Nítorí náà, nígbà tí Màta gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀: ṣùgbọ́n Màríà jòkó nínú ilé.

21. Nígbà náà, ni Màta wí fún Jésù pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.

22. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.”

23. Jésù wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.”

24. Màta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.”

25. Jésù wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè: ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè:

26. Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láàyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?”

27. Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa: èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kírísítì náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”

28. Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Màríà arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.”

29. Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

30. Jésù kò tíì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Màrta ti pàdé rẹ̀.

31. Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Màríà tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀.

Ka pipe ipin Jòhánù 11