Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 1:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Òun fúnrarẹ̀ kì í ṣe Ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún Ìmọlẹ̀ náà.

9. Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé.

10. Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n.

11. Ó tọ àwọn tirẹ̀ wá, àwọn tirẹ̀ kò sì gbà á.

12. Ṣùgbọ́n iye àwọn tí ó gbà á, àní àwọn náà tí ó gbà orúkọ rẹ̀ gbọ́, àwọn ni ó fi agbára fún láti di ọmọ Ọlọ́run;

13. Àwọn ọmọ tí kì íṣe nípa ẹ̀jẹ̀, tàbí nípa ti ìfẹ́ ara, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípa ìfẹ́ ti ènìyàn, bí kò ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run.

14. Ọ̀rọ̀ náà sì di ara, òun sì ń bá wa gbé. Àwa sì ti rí ògo rẹ̀, àní ògo Òun ọmọ bíbí kan ṣoṣo, àní Àyànfẹ́ rẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́.

15. Jòhánù sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀ jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ”

16. Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún.

17. Nítorí pé nípaṣẹ̀ Mósè ni a ti fi òfin fún ni; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ ti ipaṣẹ̀ Jésù Kírísítì wá.

18. Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọ́run rí, ṣùgbọ́n Òun, àní Àyànfẹ́ rẹ̀ kan ṣoṣo, tí ń bẹ ní oókan àyà Baba, Òun náà ni ó fi í hàn.

19. Èyí sì ni ẹ̀rí Jòhánù, nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì láti Jérúsálẹ́mù wá láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ẹni tí òun ń ṣe.

20. Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kírísítì náà.”

21. Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta há ni ìwọ? Èlíjà ni ìwọ bí?”Ó sì wí pé, “Èmi kọ́,”“Ìwọ ni wòlíì náà bí?”Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”

22. Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀ wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ í ṣe? Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ. Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ?”

Ka pipe ipin Jòhánù 1