Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 1:20-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Òun kò sì kùnà láti jẹ́wọ́, ṣùgbọ́n òun jẹ́wọ́ wọ́ọ́rọ́wọ́ pé, “Èmi kì í ṣe Kírísítì náà.”

21. Wọ́n sì bi í léèrè pé, “Ta há ni ìwọ? Èlíjà ni ìwọ bí?”Ó sì wí pé, “Èmi kọ́,”“Ìwọ ni wòlíì náà bí?”Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”

22. Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀ wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ í ṣe? Fún wa ní ìdáhùn kí àwa kí ó lè mú èsì padà tọ àwọn tí ó rán wa wá lọ. Kí ni ìwọ wí nípa ti ara rẹ?”

23. Jòhánù sì fi ọ̀rọ̀ wòlíì Àìṣáyà fún wọn ní èsì pé, “Èmi ni ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà Olúwa ní títọ́.’ ”

24. Ọ̀kan nínú àwọn Farisí tí a rán

25. bi í léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fí ń bamitíìsì nígbà náà, bí ìwọ kì í bá ṣe Kírísítì, tàbí Èlíjà, tàbí wòlíì náà?”

26. Jòhánù dá wọn lóhùn, wí pé, “Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi: ẹnìkan dúró láàárin yín, ẹni tí ẹ̀yin kò mọ̀;

27. Òun náà ni ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹni tí èmi kò tó láti tú.”

28. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Bétanì ní òdì kejì odò Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣe ìtẹ̀bọmi.

29. Ní ọjọ́ kejì Jòhánù rí Jésù tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!

30. Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi pọ̀ jù mí lọ nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’

31. Èmi gan-an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Ísírẹ́lì.”

32. Nígbà náà ni Jòhánù jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mi sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e.

33. Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitíìsì sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitíìsì.’

34. Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”

Ka pipe ipin Jòhánù 1