Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jákọ́bù 2:13-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nítorí ẹni tí kò ṣàánú, ni a ó ṣe ìdájọ́ fún láìsí àánú; àánú ń ṣògo lórí ìdájọ́.

14. Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí?

15. Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́,

16. Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́?

17. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀.

18. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni lè wí pé, “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́:”Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi.

19. Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wá rìrì.

20. Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni?

21. Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Ábúrámù baba wa láre, nígbà tí ó fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ?

22. Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé.

23. Ìwé mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, “Ábúrámù gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un,” a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

24. Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan.

25. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú kí a dá Ráhábù panṣágà láre nípa iṣẹ́ bí, nígbà tí ó gba àwọn amí, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn?

26. Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.

Ka pipe ipin Jákọ́bù 2