Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 7:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn èyí ni mo rí ańgẹ́lì mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí òkun, tàbí sára igikígi.

2. Mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-òòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́: ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà tí a fifún un láti pa ayé, àti òkun, lára,

3. Wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.”

4. Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si: Àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje o lé ẹgbàájì láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá.

5. Láti inú ẹ̀yà Júdà a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Reubẹ́nì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Gádì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.

6. Láti inú ẹ̀yà Ásérì a fi èdídí sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Nefítalímù a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Mánásè a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.

7. Láti inú ẹ̀yà Simeónì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Léfì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Ísakárì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.

8. Láti inú ẹ̀yà Sebulúnì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Jósẹ́fù a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.Láti inú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì a fi èdìdì sàmì sí ẹgbàá mẹ́fà.

9. Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsí i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn.

Ka pipe ipin Ìfihàn 7