Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 6:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfa mo sì rí i, sì kíyèsí i, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; ọ̀run sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òsùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀;

13. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í.

14. A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùsù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn.

15. Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olókúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè;

16. Wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà:

17. Nítorí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn dé; ta ni sì le dúró?”

Ka pipe ipin Ìfihàn 6