Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 6:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà sí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, “Wá, wò ó!”

2. Mo sì wò ó, kíyèsí i, Ẹṣin funfun kan: ẹni tí ó sì jókòó lórí i rẹ̀ ní ọrùn kan; a sì fi adé kan fún un: ó sì jáde lọ láti ìṣẹ́gun dé ìsẹ́gun.

3. Nígbà tí ó sì sí èdìdì kéjì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, “Wá, wò ó!”

4. Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde: a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn: A sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́.

5. Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹ́tà, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, Wá, wò ó. Mo sì wò ó, sì kíyèsí i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí ni ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀.

6. Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárin àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òsùwọ̀n àlìkámà kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà-bálì mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsí i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára.

7. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹ́rin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, Wá wò ó.

8. Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹ̀ṣin ràndànràndàn kan: orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ̀yìn. A sì fi agbára fún wọn lórí ìdá mẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa.

9. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìmú:

Ka pipe ipin Ìfihàn 6