Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 2:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Sí Ańgẹ́lì Ní Éfésù kọ̀wé:Nǹkan wọ̀nyí ní ẹni tí ó mú ìràwọ̀ méje náà ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ẹni tí ń rìn ní àárin ọ̀pá wúrà fìtílà méje:

2. Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú: àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní àpósítélì, tí wọ́n kì í sì í se bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n;

3. Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọjú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.

4. Ṣíbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹsílẹ̀.

5. Rántí ibi tí ìwọ ti gbé subú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìsáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì sí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà.

6. Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikoláétánì, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.

7. Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mi ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìye nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrin Párádísè Ọlọ́run.

8. “Àti sí Ańgẹ́lì Ìjọ ní Símírínà Kọ̀wé:Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni-ìṣáájú àti ẹni-ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè:

9. Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́ èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé Júù ni àwọn tìkárawọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ sínágọ́gù ti Sátánì.

Ka pipe ipin Ìfihàn 2