Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 18:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé:“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,Bábílónì ìlú alágbára nì!Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’

11. “Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń sọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́:

12. Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti pẹ́rílì, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti sẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabílì.

13. Àti ti Kínamónì, àti ti onírúurú ohun olóòórun dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti oróro, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti àlìkámà, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹ̀sin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn.

14. “Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kufẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé.

15. Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè rére nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ oró rẹ̀, wọn o máa sọ́kún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀,

16. Wí pé:“ ‘Ẹ̀gbẹ́! Ẹ̀gbé, ni fún ìlú ńlá nì,tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́,àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe lọ́sọ̀ọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti pẹrílì!

17. Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’“Àti olúkulùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ìbikíbí, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú òkun dúró ní òkèrè réré,

18. Wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’

19. Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ní òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.

20. Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!Àti ẹ̀yin Àpósítélì mímọ́ àti wòlíì!Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Ìfihàn 18