Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 16:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti inú tẹ́ḿpìlì wá, ń wí fún àwọn ańgẹ́lì, méje nì pé, “Ẹ lọ, ẹ sì tú ìgò ìbínú Ọlọ́run wọ̀nnì sí orí ayé.”

2. Èkínní sì lọ, ó sì tú ìgò tirẹ̀ sí orílẹ̀ ayé: egbò kíkẹ̀ tí ó sì díbàjẹ́ sì dá àwọn ènìyàn tí ó ní àmì ẹranko náà, àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀.

3. Èkejì sì tú ìgò sínú òkun; ó sì dàbí ẹ̀jẹ̀ òkú ènìyàn: gbogbo ọkàn alàyè sì kú nínú òkun.

4. Ẹ̀kẹ́ta sì tú ìgò tirẹ̀ sínú odò, àti sí orísun àwọn omi; wọ́n sì di ẹ̀jẹ̀.

5. Mo sì gbọ́ ańgẹ́lì ti omi wí pé:“Olódodo ni ìwọ Ẹni Mímọ́ ẹni tí ó ń bẹ,tí ó sì ti wà,nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ báyìí.

6. Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀,ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yìí ní ó yẹ wọ́n.”

7. Mo sì gbọ́ pẹpẹ ń ké wí pé:“Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.”

8. Ẹ̀kẹrin sì tú ìgò tirẹ̀ sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára.

9. A sì fi oru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un.

10. Ẹ̀karùn-ún sì tú ìgo tirẹ̀ sórí ìtẹ ẹranko náà; ilẹ̀ ọba rẹ̀ sì sókùnkùn; wọ́n sì ń gé ahọ́n wọn jẹ́ nítorí ìrora.

11. Wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ọ̀run nítorí ìrora wọn àti nítorí egbò wọn, wọ́n kò sì ronupìwàdà iṣẹ́ wọn.

12. Ẹ̀kẹfà sì tu ìgò tirẹ̀ sórí odò ńlá Yúfúrátè; omi rẹ̀ sì gbẹ, kí a lè pèṣè ọ̀nà fún àwọn ọba láti ìlà òòrùn wá.

13. Mo sì rí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ mẹ́ta bí ọ̀pọ̀lọ́, wọ́n ti ẹnu dírágónì náà àti ẹnu ẹranko náà àti ẹnu wòlíì èké náà jáde wá.

Ka pipe ipin Ìfihàn 16