Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 14:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí-wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà láìní àbùlà sínú ago ìrúnnú rẹ̀; a ó sì fi iná sufúrù dá a lóró níwájú àwọn ańgẹ́lì mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn:

11. Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀.”

12. Nihìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jésù mọ́.

13. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.”Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sìnmí kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.”

14. Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkúùkùu àwọsánmà funfun kan, àti lóri ìkúùkùu àwọ̀sánmà náà ẹnikan jókòó tí o “dàbí Ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀.

15. Ańgẹ́lì mìíràn sì tí inú tẹḿpìlì jáde wa tí ń ké lóhùn rara sí ẹni tí ó jókòó lórí ìkúùkùu àwọsánmà náà pé, “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí ó sì máa kórè; nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.”

16. Ẹni tí ó jókòó lórí ìkúùkùu àwọsánmà náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ orí ilẹ̀ ayé; a sì ṣe ìkórè ilẹ̀ ayé.

17. Ańgẹ́lì mìíràn sì tí inú tẹmpílì tí ń bẹ ni ọ̀run jáde wá, òun pẹ̀lú sì ní dòjé mímú, kan.

18. Ańgẹ́lì mìíràn sì tí ibi pẹpẹ jáde wá, tí ó ní agbára lórí iná; ó sì ké ni ohùn rara sí ẹni tí o ni dòjé mímú náà, wí pé, “Tẹ dòjé rẹ mímú bọ̀ ọ́, ki ó sì rẹ̀ àwọn ìdí àjàrà ayé, nítorí àwọn èso rẹ̀ tí pọ́n.”

19. Ańgẹ́lì náà sì tẹ dòjé rẹ̀ bọ ilẹ́ ayé, ó sì gé àjàrà ilẹ́-ayé, ó sì kó o lọ sínú ìfúntì, ìfúntí ńlá ìbínú Ọlọ́run.

20. A sì tẹ ìfúntí náà lẹ́yìn òde ilú náà, ẹ̀jẹ̀ sì ti inú ìfúntí náà jáde, ó sì ga sókè dé okùn ìjánu ẹṣin, èyí tí ìnàsílẹ̀ rẹ to ẹ̀gbẹjọ̀ ibùsọ̀.

Ka pipe ipin Ìfihàn 14