Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí-wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà láìní àbùlà sínú ago ìrúnnú rẹ̀; a ó sì fi iná sufúrù dá a lóró níwájú àwọn ańgẹ́lì mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn: