Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9:37-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òké.

38. Bí Lídà sì ti súnmọ́ Jópà, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹyìn gbọ́ pé Pétérù wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé lọ́dọ̀ wa.”

39. Pétérù sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí ìyará òkè náà: gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọ́kásì dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn.

40. Ṣùgbọ́n Pétérù ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tàbítà, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀: nígbà tí ó sì rí Pétérù, ó dìde jókòó.

41. Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi i lé wọn lọ́wọ́ láàyè.

42. Èyí sì di mímọ̀ já gbogbo Jópà; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́.

43. Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Jópà ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Símónì oníṣọ̀nà-awọ.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9