Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9:21-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fòórò àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerúsálémù? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhìnyìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.”

22. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Dámásíkù, ó fi hàn pé, èyí ni Kírísítì náà.

23. Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á

24. Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mímọ̀ fún Ṣọ́ọ̀lù. Wọ́n sì ń sọ́ ẹnu-bodè pẹ̀lú lọ́san àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á.

25. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.

26. Nígbà ti Ṣọ́ọ̀lù sì de Jerúsálémù ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni.

27. Ṣùgbọ́n Bánábà mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn àpósítélì, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Dámásíkù ní orúkọ Jésù.

28. Ó sì pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerúsálémù.

29. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Jésù Olúwa, ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Hélénì, ó sì ń jà wọ́n níyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a.

30. Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesaríà, wọ́n sì rán an lọ sí Tásísì.

31. Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Jùdíà àti ni Gálílì àti ni Samaríà, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i

32. Ó sì ṣe, bí Pétérù ti ń kọjá lọ káàkiri láàrin wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lídà.

33. Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Áénéà tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní àrùn ẹ̀gbà.

34. Pétérù sì wí fún un pé, “Áénéà, Jésù Kírísítì mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà.

35. Gbogbo àwọn tí ń gbé Lídà àti Sárónì sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa.

36. Ọmọ-ẹyìn kan sí wà ní Jópà ti a ń pè ni Tàbítà, èyí tí ó túmọ̀ sí Dọ́kásì; obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ-àánú ṣíṣe.

37. Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òké.

38. Bí Lídà sì ti súnmọ́ Jópà, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹyìn gbọ́ pé Pétérù wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé lọ́dọ̀ wa.”

39. Pétérù sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí ìyará òkè náà: gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọ́kásì dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn.

40. Ṣùgbọ́n Pétérù ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tàbítà, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀: nígbà tí ó sì rí Pétérù, ó dìde jókòó.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9