Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 8:18-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nígbà tí Símónì rí i pé nípa gbígbe ọwọ́ leni ni a ń ti ọwọ́ àwọn àpósítélì fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n,

19. ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”

20. Ṣùgbọ́n Pétérù dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!

21. Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déedé níwájú Ọlọ́run.

22. Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búrurú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dári ète ọkàn rẹ jì ọ́.

23. Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹrò ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”

24. Nígbà náà ni Símónì dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”

25. Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, ti wọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Pétérù àti Jòhánù padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì wàásù ìyìn rere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn Samaríà.

26. Ańgẹ́lì Olúwa sì sọ fún Fílípì pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerúsálémù lọ sí Gásà.”

27. Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsí, ọkùnrin kan ará Etiópíà, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọdọ̀ Káńdákè ọba-bìnrin àwọn ara Etiópíà, ẹni tí í se olórí ìsúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerúsálémù láti jọ́sìn,

28. Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà.

29. Ẹ̀mí sì wí fún Fílípì pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.”

30. Fílípì si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Àìṣáyà, Fílípì sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?”

31. Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Fílípì kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó.

32. Ibi-ìwé-mímọ́ tí Ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí:“A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa;àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olúrẹ́run rẹ̀,bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 8