Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7:57-60 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

57. Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú,

58. wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Sọ́ọ̀lù.

59. Bí wọ́n ti ń sọ ọ́ ní òkúta, Sítéfánù gbàdúrà wí pé, “Jésù Olúwa, gba ẹ̀mi mi.”

60. Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7