Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7:46-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

46. Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jákọ́bù.

47. Ṣùgbọ́n Sólómónì ni ó kọ́ ilé fún un,

48. “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:

49. “ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,ayé ni àpòtí ìtìsẹ̀ mi.Irú ilé kínní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi?ni Olúwa wí.Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi isinmi mi?

50. Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 7