Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5:2-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apákan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apákan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn àpósítélì.

3. Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, “Ananíyà, È é ṣe ti sátánì fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí-Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apákan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà?

4. Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? È é há ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣékè sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?”

5. Nígbà tí Ananíyà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó subú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́.

6. Àwọn ọdọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín.

7. Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé.

8. Pétérù sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Ananíyà gbà lórí ilẹ̀?”Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ nìyẹn.”

9. Pétérù sí wí fún un pé, “È é ṣe ti ẹ̀yin fohùn sọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Mímọ́ wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ lẹ́nu ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”

10. Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bá ọkọ rẹ̀.

11. Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.

12. A sì ti ọwọ́ àwọn àpósítélì ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrin àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Sólómónì.

13. Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn.

14. Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i.

15. Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí bẹ́ẹ̀dì àti ẹní kí òjìji Pétérù ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ.

16. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerúsálémù ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.

17. Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlúfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sádúsì wọ̀.

18. Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn àpósítélì wọn sì fi wọ́n sínú túbú.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 5