Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4:32-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì sí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìsọ̀kan.

33. Agbára ńlá ni àwọn àpósítélì sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jésù Olúwa, Oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn.

34. Nítorí kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó ṣe aláìní, nítorí iye àwọn tí ó ní ilẹ̀ tàbí ilé tà wọ́n, wọ́n sì mú owó ohun tí wọn tà wá.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4