Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4:2-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Inú bí wọn, nítorí tí wọn kọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń wàsúù àjíǹde kúrò nínú òkú nínú Jésù.

3. Wọn sì náwọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ijọ́ kejì; nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan.

4. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́; iye àwọn ọkùnrin náà sì tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5000).

5. Ó sì ṣe níjọ kejì, àwọn olórí wọn àti àwọn alàgbà àti àwọn olùkọ́ni ní òfin péjọ sí Jerúsálémù.

6. Àti Ánà olórí àlùfáà, àti Káíáfà, àti Jòhánù, àti Alekisáńdérù, àti iye àwọn tí i ṣe ìbátan olórí àlùfáà.

7. Wọ́n mú Pétérù àti Jòhánù dúró níwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Nípa agbára tàbí orúkọ wo ni ẹ̀yin fi ṣe èyí?”

8. Nígbà náà ni Pétérù kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin olórí àti ẹ̀yin alàgbà àwọn ènìyàn!

9. Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónì ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá,

10. Kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì pé, ni orúkọ Jésù Kírísítì ti Násárétì, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá.

11. Èyí ni“ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’

12. Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlomìíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fifún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.”

13. Nígbà tí wọ́n sì kíyèsí ìgboyà Pétérù àti Jòhánù, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jésù gbé.

14. Nígbà tí wọ́n sì ń wo ọkùnrin náà tí a mú láradá, tí ó bá wọn dúró, wọn kò rí nǹkan wí sí i.

15. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sì ti pàṣẹ pé kí wọn jáde kúrò ní ìgbìmọ̀, wọ́n bá ara wọn gbérò.

16. Wí pé, “Kí ni a ó ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí? Ní ti pé iṣẹ́ àmì tí ó dájú tí ọwọ́ wọn ṣe, ó hàn gbangba fún gbogbo àwọn tí ń gbé Jerúsálémù; àwa kò sì lè ṣe èyí.

17. Ṣùgbọ́n kí ó má ba à tàn kálẹ̀ ṣíwájú mọ́ láàrin àwọn ènìyàn, ẹ jẹ́ kí a kìlọ̀ fún wọn pé, láti ìsinsin yìí lọ kí wọn má ṣe fi orúkọ yìí sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni mọ́.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 4