Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 28:19-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù sọ̀rọ̀ lòdì sí i, èyí sún mí láti fi ọ̀ràn náà lọ Késárì, kì í ṣe pé mo ní ẹ̀sùn kan láti fi kan àwọn ènìyàn mi.

20. Ǹjẹ́ nítorí ọ̀ràn yìí ni mo ṣe ránṣẹ́ pè yín, láti rí yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ nítorí pé, nítorí ìrètí Ísírẹ́lì ni a ṣe fi ẹ̀wọ̀n yìí dè mí.”

21. Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò rí ìwé gbà láti Jùdíà nítorí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan nínú àwọn arákùnrin tí ó ti ibẹ̀ wá kò ròyìn, tàbí kí ó sọ̀rọ̀ ibi kan sí ọ.

22. Ṣùgbọ́n àwa ń fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ ohun tí ìwọ rò nítorí bí ó ṣe ti ìsìn ìyapa yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”

23. Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò se ìpàdé pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jésù láti inú òfin Mósè àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́.

24. Àwọn ẹlòmíràn gba ohun tí ó wí gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn kò sì gbà á gbọ́.

25. Nígbà tí ohùn wọn kò ṣọ̀kan láàrin ara wọn, wọ́n túká, lẹ́yìn ìgbà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ kan pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ sọ òtítọ́ fún àwọn baba yín nígbà tí ó sọ láti ẹnu wòlíì Àìṣáyà wí pé:

26. “ ‘Tọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ, kí ó sì wí pé,“Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;à ti ni rírí ẹ̀yin yóò rí, ẹ kì yóò sí òye lati mọ̀.”

27. Nítorí ti àyà àwọn ènìyàn yìí yigbì,etí wọn sì wúwo láti fi gbọ́,ojú wọn ni wọn sì ti di.Nítorí kí wọn má ba à fi ojú wọn rí,kí wọn má ba à fi etí wọn gbọ́,àti kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀,kí wọn má ba à yípadà, àti kí èmi má ba à mú wọn láradá.’

28. “Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin mọ́ èyí pé, a rán ìgbàlà Ọlọ́run sí àwọn Kèfèrì wọ́n ó sì gbọ́.

29. Nígbà tí ó ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wọn tan, àwọn Júù lọ, wọ́n bá ara wọn jíyàn púpọ̀.”

30. Pọ́ọ̀lù sì gbé ilé àgbàwọ̀ rẹ̀ lọ́dún méjì gbáko, ó sì ń gbà gbogbo àwọn tí ó wọlé tọ̀ ọ́ wá.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 28