Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 27:20-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Nígbà tí òòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.

21. Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Pọ́ọ̀lù dìde láàrin wọn, ó ní, “Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Kírétè, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa.

22. Ǹjẹ̀ nísinsìn yìí mó gbà yín níyànjú, kí ẹ tújúká; nítorí kí yóò sí ẹni tí yóò nù, bí kò ṣe ti ọkọ̀.

23. Nítorí ańgẹ́lì Ọlọ́run, ẹni tí èmi jẹ́ tirẹ̀, àti ẹni ti èmi ń sìn, ó dúró tì mi ni òru àná.

24. Ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Pọ́ọ̀lù; ìwọ kò lè ṣàìmá dúró níwájú Késárì: Sì wò ó, Ọlọ́run ti fi gbogbo wọn ti ó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ fún ọ.’

25. Ǹjẹ́ nítorí náà, alàgbà, ẹ dárayá: nítorí mo gba Ọlọ́run gbọ̀ pé, yóò rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún mi.

26. Ṣùgbọ́n a ó gbá wa jù sí erékùṣù kan.”

27. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru ọjọ́ kẹrìnlá, bí a ti ń gbé wa kọjá lọ láàrin òkun Ádíríà, láàrin ọ̀gànjọ́ àwọn atukọ̀ fura pé, àwọn súnmọ́ etí ilẹ̀ kan:

28. Nígbà tí wọ́n sì wọn òkun, wọ́n rí i ó jìn ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún ṣíwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn òkun, wọn rí i pé ó jìn ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógùn.

29. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ro mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí-ọkọ̀, wọ́n ń rétí òjúmọ́.

30. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ ìgbàjá kalẹ̀ sí ojú òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀.

31. Pọ́ọ̀lù wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!”

32. Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun gé okùn ìgbàjá, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣúbu sọ́hun.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 27