Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 26:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Sátanì ṣí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ̀ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’

19. “Nítorí náà, Àgírípà ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà.

20. Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Dámásíkù, àti ní Jerúsálémù, àti já gbogbo ilẹ Jùdíà, àti fún àwọn Kèfèrì, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwadà.

21. Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù ṣe gbá mi mú nínú tẹ́ḿpílì, tí wọ́n sì ń fẹ́ pá mí.

22. Ṣùgbọ́n bí mo sì tí ri ìrànlọ́wọ́ gbà láti lọ́dọ̀ Ọlọ́run, mo dúró títí ó fí di òní, mo ń jẹ́rìí fún àti èwe àti àgbà, èmi kò sọ ohun mìíràn bí kò ṣe ohun tí àwọn wòlíì àti Móṣè tí wí pé, yóò ṣẹ:

23. Pé, Kírísítì yóò jìyà, àti pé Òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, Òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn Kèfèrì.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 26