Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23:23-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ ṣí Kesaríà, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹ́ta òru.

24. Ó sì wí pé, kí wọn pèṣè ẹranko, kí wọ́n gbé Pọ́ọ̀lù gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Fẹ́líkísì baálẹ̀ ní àlàáfíà.”

25. Ó sì kọ ìwé kan báyìí pé:

26. Kíláúdíù Lísíà,Sí Fẹ́líkísì baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ:Àlàáfíà.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 23