Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20:24-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ṣùgbọn èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan rárá bi ohun tí ó sọ̀wọ́n fún mi àti iṣẹ́-ìránṣẹ́ tí mo tí gbà lọ́dọ̀ Jésù Olúwa, láti máa ròyìn ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọ̀lọ́run.

25. “Ǹjẹ́ nísìnsìn yìí, wò ó, èmi mọ̀ pé gbogbo yín, láàrin ẹni tí èmi tí ń kiri wàásù ìjọba Ọlọ́run, kì yóò rí ojú mi mọ́.

26. Nítorí náà mo pè yín ṣe ẹlẹ́rìí lónìí yìí pé, ọrùn mi mọ́ kúró nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo.

27. Nítorí tí èmi kò fà ṣẹ́yìn láti ṣọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún un yin.

28. Ẹ kíyèsára yin, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábòójútó rẹ̀, láti máa tọ́jú ìjọ Ọlọ́run, tí ó tí fi ẹ̀jẹ̀ (ọmọ) rẹ̀ rà.

29. Nítorí tí èmi mọ̀ pé, lẹ́yìn lílọ̀ mi, ìkookò búburú yóò wọ àárin yín, yóò sì tú agbo ká.

30. Láàrin ẹ̀yin tìkárayín ni àwọn ènìyàn yóò sì dìde, tí wọn yóò máa sọ̀rọ̀-òdì, láti fa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sẹ́yìn wọn.

31. Nítorí náà ẹ máa sọ́ra, ki ẹ sì máa rántí pé, fún ọdún mẹ́ta, èmi kò dẹ́kun láti máa fi omijé kìlọ̀ fún olúkúlùkù ní ọ̀sán àti ní òru.

32. “Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ará, mo fi yín lé Ọlọ́run lọ́wọ́ àti ọ̀rọ̀ oore-ọfẹ́ rẹ̀, tí ó lè gbé yín dúró, tí ó sì lè fún yín ní ìní láàrin gbogbo àwọn tí a sọ di mímọ́.

33. Èmí kò ṣe ojúkòkòrò fàdákà, tàbí wúrà, tàbí aṣọ ẹnikẹ́ni.

34. Ẹ̀yin tìkárayín ṣáà mọ̀ pé, ọwọ́ mi wọ̀nyí ni mo fi ṣiṣẹ́ láti fi pèsè fún àìní mi, àti tí àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi.

35. Nínú ohun gbogbo mo fi àpẹẹrẹ fún un yín pé, nípa ṣíṣe iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ki ẹ sì máa rántí ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa, bí òun tìkararẹ̀ tí wí pé, ‘láti fún ni ní ìbùkún ju láti gbà lọ.’ ”

36. Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, ó kúnlẹ̀, ó sì bá gbogbo wọn gbàdúrà.

37. Gbogbo wọn sì sọkún gidigidi, wọ́n sì rọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù lọ́rùn, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu.

38. Inú wọn sì bàjẹ́ jùlọ fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ pé, wọn kì yóò rí ojú òun mọ́, wọ́n sì sìn ín títí dé inú ọkọ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20