Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ ṣí Makedóníà.

2. Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ pupọ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Gíríkì.

3. Ó sì dúró níbẹ̀ ní osù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àtibá ọkọ̀-ojú-omi lọ sí Síríà, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedóníà padà lọ.

4. Sópátérù ará Béríà ọmọ Páríù sì bá a lọ dé Éṣíà; àti Sékúńdù; àti Gáíúṣì ará Dábè, àti Tìmótíù; ará Éṣíà, Tíkíkù àti Tírófímù.

5. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Tíróáṣì.

6. Àwa sì síkọ̀ láti Fílípì lọ lẹ́yìn ọjọ àkàrà àìwú, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Tíróáṣì ni ijọ́ méje.

7. Ọjọ́ ìkínní ọ̀ṣẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Pọ́ọ̀lù sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ijọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárin ọ̀gànjọ́.

8. Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí a gbé péjọ sí.

9. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Éútíkù sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Pọ́ọ̀lù sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n lójú oorun, ó súbù láti òkè kẹ́ta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú.

10. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbà á mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láàyè.”

11. Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ́ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ.

12. Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà bọ̀ láàyè, inú gbogbo wọn sì dún lọ́pọ̀lọpọ̀.

13. Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Ásósì, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Pọ́ọ̀lù sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkararẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹṣẹ̀ lọ.

14. Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Ásósì, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Mítílénì.

15. Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ijọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kíósì; ní ijọ́ kejì rẹ̀ a dé Sámósì, a sì dúró ní Tírógílíónì: ni ijọ́ kéjì rẹ̀ a sì dé Mílétù.

16. Pọ́ọ̀lù ṣa ti pinnu rẹ̀ láti bá ọkọ̀-ojú omi kọjá ṣí Éféṣù, nítorí ki ó má baà lo àkókò kankan ni Éṣíà: nítorí tí ó ń yára bí yóò ṣe ṣééṣe fún un láti wà ní Jerúsálémù lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sítì.

17. Ní àti Mílétù ni Pọ́ọ̀lù ti ránṣẹ́ sí Éféṣù, láti pé àwọn alàgbà ìjọ wá ṣọ́dọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20