Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ariwo náà sí rọlẹ̀, Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú, ó dágbére fún wọn, ó dìde láti lọ ṣí Makedóníà.

2. Nígbà tí ó sì tí la apá ìhà wọ̀nyí kọjá, tí ó sì ti fi ọ̀rọ̀ pupọ gbà wọ́n ní ìyànjú, ó wá sí ilẹ̀ Gíríkì.

3. Ó sì dúró níbẹ̀ ní osù mẹ́ta, nígbà tí àwọn Júù sì dènà dè é, bí ó ti ń pète àtibá ọkọ̀-ojú-omi lọ sí Síríà, ó pinnu rẹ̀ láti gbà Makedóníà padà lọ.

4. Sópátérù ará Béríà ọmọ Páríù sì bá a lọ dé Éṣíà; àti Sékúńdù; àti Gáíúṣì ará Dábè, àti Tìmótíù; ará Éṣíà, Tíkíkù àti Tírófímù.

5. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí tí lọ síwájú, wọ́n dúró dè wá ni Tíróáṣì.

6. Àwa sì síkọ̀ láti Fílípì lọ lẹ́yìn ọjọ àkàrà àìwú, a sì dé ọ̀dọ̀ wọn ní Tíróáṣì ni ijọ́ méje.

7. Ọjọ́ ìkínní ọ̀ṣẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn péjọ láti bu àkàrà, Pọ́ọ̀lù sì wàásù fún wọn, ó múra láti lọ ní ijọ́ kejì: ó sì fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di àárin ọ̀gànjọ́.

8. Fìtílà púpọ̀ sì wà ní iyàrá òkè náà, níbi tí a gbé péjọ sí.

9. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí a ń pè ní Éútíkù sì jókòó lójú fèrèsé, oorun sì wọ̀ ọ́ lára; bí Pọ́ọ̀lù sì ti pẹ́ ní ìwàásù, ó ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n lójú oorun, ó súbù láti òkè kẹ́ta wá sílẹ̀, a sì gbé e dìde ní òkú.

10. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì sọ̀kalẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ tì i, ó sì gbà á mọ́ra, ó ní, “Ẹ má ṣe yọ ara yín lẹ́nu; nítorí tí òun wà láàyè.”

11. Nígbà tí ó sì tún gòkè lọ, ó sì jẹ oúnjẹ́ Olúwa, ó sì sọ̀rọ̀ pẹ́ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́, nígbà náà ni ó sì lọ.

12. Wọ́n sì mú ọmọkùnrin náà bọ̀ láàyè, inú gbogbo wọn sì dún lọ́pọ̀lọpọ̀.

13. Nígbà ti àwa sì ṣáájú, àwa sì ṣíkọ̀ lọ sì Ásósì, níbẹ̀ ni a ti lérò láti gba Pọ́ọ̀lù sínú ọkọ̀: nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó tí pinnu rẹ̀, òun tìkararẹ̀ ń fẹ́ bá ti ọ̀nà-ẹṣẹ̀ lọ.

14. Nígbà tí ó sì pàdé wa ní Ásósì, a gbà á sínú ọkọ̀, a sì wá sí Mítílénì.

15. Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ kúrò níbẹ̀, ní ijọ́ kejì a dé ọ̀kánkán Kíósì; ní ijọ́ kejì rẹ̀ a dé Sámósì, a sì dúró ní Tírógílíónì: ni ijọ́ kéjì rẹ̀ a sì dé Mílétù.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 20