Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2:2-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó.

3. Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn.

4. Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn.

5. Àwọn Júù olùfọkànsìn láti orílẹ̀-èdè gbogbo lábẹ́ ọ̀run sì ń gbé Jerúsálémù.

6. Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ nínú ìdàmú, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀.

7. Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Gálílì kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́?

8. Èé ha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀?

9. Àwọn ará Pátíríà, àti Médísì, àti Élámù; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamíà, Júdíà, àti Kapadókíà, Pọ́ńtù, àti Ásíà.

10. Fírígíà, àti Pàḿfílíà, Íjíbítì, àti agbégbé Líbíà níhà Kírénè; àti àwọn àtìpó Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù.

11. (àti àwọn Júù àti àwọn tí a tipa ẹ̀sìn sọ di Júù); Àwọn ara Kírétè àti Árábíà; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ́rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.”

12. Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n aì wá rìrì. Wọn wí fún ara wọn pé, “Kí ni èyí túmọ̀ sí?”

13. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmìíràn ń sẹ̀fẹ̀, wọn sí wí pé, Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kún fún wáìnì titun.

14. Nígbà náà ni Pétérù díde dúró pẹ̀lú àwọn mọ́kànlá yòókù, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin Júù ènìyàn mi àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé Jerúsálémù, ẹ jẹ́ kí èyí kí ó yé yin; kí ẹ sì fétísí ọ̀rọ̀ mi.

15. Àwọn wọ̀nyí kò mutí yó, bí ẹ̀yin tí ròó; wákàtí kẹ́ta ọjọ́ sáà ni èyí.

16. Bẹ́ẹ̀ kọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ ti a ti sọ láti ẹnu wòlíì Joeli:

17. “ ‘Ní ìkẹyìn ọjọ́, Ọlọ́run wí pé,Èmi yóò tú Ẹ̀mí mí jáde sára ènìyàn gbogbo,àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín yóò sì máa ríran,àwọn arúgbó yín yóò sì máa lá àlá;

18. Àti sára àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi ọkùnrin àti sára àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mi obìnrin,ni Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi jáde ni àwọn ọjọ́ náà:wọn yóò sì máa sọtẹ́lẹ̀;

19. Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn lójú ọ̀run,àti àwọn àmì nísàlẹ̀ ilẹ̀;ẹ̀jẹ̀ àti iná àti rírú èéfín;

20. A yóò sọ òòrùn di òkùnkùn,àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ológo Olúwa tó dé.

21. Yóò sì ṣe pé ẹnikẹ́ni tí ó bá peorúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.’

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2