Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sítì sì dé, gbogbo wọn fi ọkàn kan wà ní ibìkan.

2. Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó.

3. Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn.

4. Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn.

5. Àwọn Júù olùfọkànsìn láti orílẹ̀-èdè gbogbo lábẹ́ ọ̀run sì ń gbé Jerúsálémù.

6. Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ nínú ìdàmú, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀.

7. Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Gálílì kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́?

8. Èé ha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀?

9. Àwọn ará Pátíríà, àti Médísì, àti Élámù; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamíà, Júdíà, àti Kapadókíà, Pọ́ńtù, àti Ásíà.

10. Fírígíà, àti Pàḿfílíà, Íjíbítì, àti agbégbé Líbíà níhà Kírénè; àti àwọn àtìpó Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù.

11. (àti àwọn Júù àti àwọn tí a tipa ẹ̀sìn sọ di Júù); Àwọn ara Kírétè àti Árábíà; àwa gbọ́ tí wọ́n sọ́rọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlá Ọlọ́run ni èdè wa.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2