1. Nígbà tí ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sítì sì dé, gbogbo wọn fi ọkàn kan wà ní ibìkan.
2. Lójijì ìró sì ti ọ̀run wá, gẹ́gẹ́ bí ìró ẹ̀fúùfù líle, ó sì kún gbogbo ilé níbi tí wọ́n gbé jókòó.
3. Ẹ̀là ahọ́n bí i iná sì yọ sí wọn, ó pín, ó sì bà lé olúkúlùkù wọn.
4. Gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti fi fún wọn ni ohùn.
5. Àwọn Júù olùfọkànsìn láti orílẹ̀-èdè gbogbo lábẹ́ ọ̀run sì ń gbé Jerúsálémù.
6. Nígbà tí wọn sì gbọ́ ìró yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ nínú ìdàmú, nítorí tí olúkúlùkù gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè rẹ̀.
7. Ẹnu sì yà wọ́n, wọn ń wí fún ara wọn pé, “Ǹjẹ́ ara Gálílì kọ́ ni gbogbo àwọn tí ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́?
8. Èé ha sì tí ṣe ti olúkúlùkù wa fi ń gbọ́ bí wọ́n tí ń fi èdè sọ̀rọ̀?
9. Àwọn ará Pátíríà, àti Médísì, àti Élámù; àti àwọn tí ń gbé Mesopotamíà, Júdíà, àti Kapadókíà, Pọ́ńtù, àti Ásíà.
10. Fírígíà, àti Pàḿfílíà, Íjíbítì, àti agbégbé Líbíà níhà Kírénè; àti àwọn àtìpó Róòmù, àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù.