Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yin nǹkan wọ̀nyí, Pọ́ọ̀lù jáde kúrò ni Aténì, lọ sí Kọ́ríńtì;

2. Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Àkúílà, tí a bí ni Pọ́ńtù, tí ó ti Ìtalì dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Pírísíkílà aya rẹ̀; nítorí tí Kíláúdíù pàsẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Róòmù. Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn.

3. Nítorí tí òun náà jẹ́ onísẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì nṣíṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́-ọwọ́ wọn.

4. Ó sì ń fọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ fún wọn nínú ṣínágógù lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Gíríkì lọ́kàn padà.

5. Nígbà tí Sílà àti Tímótíù sì tí Makedóníà wá, ọ̀rọ̀ náà ká Pọ́ọ̀lù lára, ó ń fi hàn fún àwọn Júù pé, Jésù ni Kírísítì náà.

6. Nígbà tí wọ́n sì sàtakò rẹ̀, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì, ó gbọ́n aṣọ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀jẹ̀ yin ń bẹ lórí ara yin; ọrùn èmi mọ́: láti ìsinsìnyìí lọ, èmi yóò tọ àwọn aláìkọlà lọ.”

7. Ó sì lọ kúrò níbẹ, ó wọ ile ọkùnrin kan tí a ń pé ní Títù Júsù, ẹni tí o ń sin Ọlọ́run; ilé rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ Sínágógù tímọ́tímọ́.

8. Kírísípù, olórí ṣínágọ́gù, sì gba Olúwa gbọ́ pẹ̀lú gbogbo ilé rẹ̀: àti ọ̀pọ̀ nínú àwọn ara Kọ́ríńtì, nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbàgbọ́, a sì bamitíìsì wọn.

9. Olúwa sì sọ fún Pọ́ọ̀lù lóru ni ojúran pé, “Má bẹ̀rù, sá máa sọ, má sì se pá ẹnu rẹ̀ mọ́:

10. Nítorí tí èmí wà pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹni tí yóò dìde sí ọ láti pa ọ lára: nítorí mo ní ènìyàn púpọ̀ ni ìlú yìí.”

11. Ó sì jókòó níbẹ̀ ní ọdun kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàrin wọn.

12. Nígbà tí Gálíónì sì jẹ báalẹ̀ Ákáyà, àwọn Júù fi ìfìmọ̀ṣọ̀kan dide sí Pọ́ọ̀lù wọn sì mú un wá síwájú ìtẹ́ ìdájọ́.

13. Wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, láti máa sin Ọlọ́run lòdì sí òfin.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18